Ìwé Wòlíì Jeremáyà 49:1-39 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Nípa ti Ámónì: Ohun tí OLÚWA sọ nìyìí: “Ísírẹ́lì kò ha ní ọmọkùnrin? Ṣé kò ha ní àrólé bí? Kí ló wá dé tí Mákómù fi jogún Gádì? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?

2Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni OLÚWA wí; “nígbà tí èmi yóò mú ìdágìrì ogun bá Rábà tí Ámónì yóò sì di òkítì ahoro, gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì yóò lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,” ni OLÚWA wí.

3“Pohùnréré ẹkún ìwọ Hésíbónì nítorí Áì tí rún, kígbe jáde ẹ̀yin ènìyàn Rábà, ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀. Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà nítorí Mákómù yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.

4Kí ló dé tí ẹ fi ń fi àfonífojì yín yangàn? Ẹ fi àfonífojì yín yangàn pẹ̀lú èṣo rere, ẹ̀yin ọmọbìnrin aláìsòótọ́. Gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé, ‘ta ni yóò kò mí lójú?’

5Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,” ni OLÚWA wí:

6“OLÚWA àwọn ọmọ ogun. Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì sí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ámónì padà,” ni OLÚWA wí.

7ⓑ Nípa Édómù: Èyí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temánì? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?

8Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò, ìwọ tí ó ń gbé ní Dédánì nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Ísọ̀ ní àkókò tí èmi ó fìyà jẹ́ẹ́.

9Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá; ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀? Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?

10Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Ísọ̀ sí ìhòòhò èmi kò ní bo ibi ìkọ̀kọ rẹ nítorí kí o máa baà fi ara rẹ pamọ́. Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti àwọn ará ilé rẹ yóò parun. Wọn kò sì ní sí mọ́.

11Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀ èmi yóò dábòbo ẹ̀mí wọn. Àwọn opó rẹ gan an lè gbékẹ̀lẹ́ mi.”

12Èyí ni ohun tí OLÚWA wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ife náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mu un.

13Èmi fi ara mi búra ni OLÚWA wí, wí pé, “Bósírà yóò bayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ẹgún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”

14Èmi ti gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ OLÚWA: A rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀ èdè láti sọ. Ẹ kó ara yín jọ láti dojúkọ ọ́, ẹ dìde fún ogun.

15“Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrin orílẹ̀ èdè gbogbo; ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn ènìyàn.

16Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta tí o jòkó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni OLÚWA wí.

17“Édómù yóò di ahoro gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ

18Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sódómù àti Gòmórà pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ,” ní OLÚWA wí. “Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀; kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.

18

19“Bí kìnnìún ti ń bọ̀ láti igbó Jódánì wá sí pápá oko ọlọ́rà á èmi yóò lé Édómù láti ibi ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni ẹni náà tí èmi yóò yàn fún èyí? Ta lo dàbí èmi, ta ni ó le pè mí níjà? Ta ni olùsọ́ àgùntàn náà tí ó lè dúró níwájú mi?”

20Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLÚWA ní fún Édómù, ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Témánì. Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde. Pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.

21Nípa ìṣubú ariwo wọn, ilẹ̀ yóò mì, a ó gbọ́ igbe wọn ní òkun pupa.

22Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀, yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bóráṣà. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun Édómù yóò dàbí ọkan obìnrin tí ń rọbí.

23Nípa Dámásíkù: “Inú Hámátì àti Árípádì bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn, wọ́n sì dààmú bí omi òkun.

24Dámásíkù di aláìlera, ó pẹ̀yindà láti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a, ìbẹ̀rù àti ìrora dì í mú, ìrora bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.

25Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀; ìlú tí mo dunnú sí.

26Lóòtọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,” ní OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí.

27“Èmi yóò fi iná sí odi Dámásíkù, yóò sì jó gbọ̀ngàn Bẹni-hádádì run.”

28Nípa Kédárì àti ìjọba Ásọ́rì èyí ti Nebukadinésárì Ọba Bábílónì dojú ìjà kọ: Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ: “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ kédárì, kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà oòrùn run.

29ⓒ Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọn yóò di gbígbà; ilé wọn yóò di ìsínípò padà pẹ̀lú ẹrù àti ràkúnmí wọn. Àwọn ọkùnrin yóò ké pè wọ́n; ‘Ìparun ní ibi gbogbo.’

29

30“Sálọ kíákíá, dúró nínú ihò ìwọ tí ò ń gbé Ásórì,” báyìí ni OLÚWA wí. “Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ti dojú ìjà kọ ọ́.

30

31“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀ èdè kan pẹ̀lú ìrọ̀rùn, èyí tí ó dúró pẹ̀lú ìgboyà;” báyìí ní OLÚWA wí. “Orílẹ̀ èdè tí kò ní yálà gbàgede tàbí irin, àwọn ènìyàn re ń dágbé.

32Àwọn ràkunmí á di ẹrù àti àwọn agbo àgùntàn, wọ́n á di ìkógun. Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́. Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,” báyìí ní OLÚWA wí.

33“Ásọ́rì yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akáta, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé, kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”

34Èyí ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyí tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá nípa Élámù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekáyà Ọba Júdà:

35Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ: “Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Élámù, ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.

36Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé lòdì sí Élámù. Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin àti pé, kò sí orílẹ̀ èdè tí ilẹ̀ àjèjì Élámù kò ní lọ.

37Èmi yóò kẹ́gàn Élámù lójú àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń gbé. Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn, pàápàá ìbínú gbígbóná mi;” bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA wí. “Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.

38Èmi yóò sì pa Ọba wọn run àti olórí wọn,” báyìí ni OLÚWA wí.

39“Ṣíbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Ẹ́lámù padà láìpẹ́ ọjọ́,” báyìí ni OLÚWA wí.

icle>