Ìwé Wòlíì Jeremáyà 50:1-46 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi sẹ́nu Jeremáyà láti sọ fún ará ilẹ̀ Bábílónì:

2“Ẹ sọ ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde, kí ẹ sì gbé àṣíà sókè. Ẹ kede, ẹ má sì ṣe bòó wí pé, ‘a kó Bábílónì, ojú tí Bélì, a fọ́ Merodákì túútúú, ojú ti àwọn ère rẹ̀, a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’

3Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò sì máa gbógun tì wọ́n. Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò sá kúrò ní ìlú yìí.

3

4“Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,” ni OLÚWA wí, “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jùmọ̀ wá, àwọn, àti àwọn ọmọ Júdà, wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́ri OLÚWA Ọlọ́run wọn

5Wọn ó máa bèèrè ọ̀nà Síhónì, oju wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ OLÚWA ní májẹ̀mú ayé-rayé, tí a kì yóò gbàgbé.

5

6“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn sìnà, wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré, wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.

7Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ àwọn ọ̀ta wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi nítorí pé wọ́n ti sẹ̀ sí OLÚWA ibùgbé òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’

7

8“Jáde kúrò ní Bábílónì fi ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì sílẹ̀ kí ẹ sì dàbí àgùntàn inú agbo tí à ń kó jẹ̀.

9Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Bábílónì àwọn orílẹ̀ èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀; Láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni alákíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo

10A ó dààmú Bábílónì, gbogbo àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú ìfẹ́ wọn sẹ,” ni OLÚWA wí.

10

11“Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀, ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn fi ayọ̀ fò bí ẹgbọ̀rọ̀ màlúù sí koríko tútù, ẹsì ń yan bí akọ-ẹsin.

12Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ yóò sì gba ìtìjú. Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀ èdè, ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ihà tí kò lọ́ràá.

13Nítorí ìbínú OLÚWA, kì yóò ní olùgbé; ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Bábílónì yóò fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.

13

14“Dúró sí àyè rẹ ìwọ Bábílónì àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ta ọfà náà. Ẹ ta ọfà náà síi, nítorí ó ti sẹ̀ sí OLÚWA.

15Kígbe mọ-ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san OLÚWA, gbẹ̀san lára rẹ̀. Ṣe síi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmìíràn.

16Mú kúrò ní Bábílónì olùgbìn àti olùkórè pẹ̀lú ohun ìkórè rẹ̀. Nítorí idà àwọn aninilára jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, kí oníkálukú sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.

16

17“A ti fọ́n Ísírẹ́lì ká, Kìnnìún sì ti lé e lọ. Ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ jẹ ẹ́ ni Ọba Ásíríà, ẹni tí ó sì jẹ eegun rẹ̀ kẹ́yìn ni Nebukadinésárì Ọba Bábílónì.”

18Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run alágbára Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; “Ǹ ó fi ìyà jẹ Ọba Bábílónì àti ilẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ Ọba, Ásíríà.

19Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Ísírẹ́lì padà wá pápá oko tútù rẹ̀ òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí kámẹ̀lì àti Básánì, a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè Éfúráímù àti ní Gílíádì

20Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni OLÚWA wí, “À ó wá àìṣedéédé ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n a ki yóò rí ìkankan; àti ẹṣẹ Júdà a ki yóò sì rí wọn nítorí èmi yóò dáríjìn àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dásí.

20

21“Kọlu ilẹ̀ Mérátamù àti àwọn tí ó ń gbé ní Pékódì. Kọlùú pa á, kí o sì párun pátapáta,” ni OLÚWA wí “Ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ.

22Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀rẹ̀ ìparun ńlá.

23Wo bi ilé ayé ti pín sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ tó. Wo bí Bábílónì ti di aláìlólùgbé ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè.

24Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Bábílónì, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako OLÚWA.

25OLÚWA ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé OLÚWA Ọlọ́run ọmọ ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Bábílónì.

26Ẹ dìde sí láti ilẹ̀ jínjín párun pátapáta láìṣẹ́kù.

27Pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn rẹ̀, jẹ́ kí a kó wọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n! Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé, àkókò ìbẹ̀wò wọn.

28Tẹ́tí sí àwọn tí ó sálọ tí ó sì sálà láti Bábílónì, sì sọ ní Síónì, bí OLÚWA Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san, ẹ̀san fún tẹ́ḿpílì rẹ̀.

28

29“Pe ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Bábílónì, ẹ doti iyikakiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà. Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbógbó èyí ti o ti ṣé, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ síi, nítorí tí ó ti gberaga sí OLÚWA, sí Ẹni-MÍMỌ̀ Ísirẹ́lì.

30Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́,” ní OLÚWA wí.

31“Wò ó, èmi lòdì sí àwọn onígbéraga,” ni OLÚWA Ọlọ́run, “ọmọ ogun wí, nítorí ọjọ́ rẹ ti dé tí ìwọ yóò jìyà.

32Onígbéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò gbé dìde. Èmi yóò tan iná ní ìlú náà, èyí tí yóò sì jo run.”

33Èyí ni ohun tí OLÚWA alágbára sọ: “A pọ́n àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lójú àti àwọn ènìyàn Júdà pẹ̀lú. Gbogbo àwọn tí ó kó wọn nígbèkùn dì í mú ṣinṣin wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálá.

34Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, OLÚWA Ọlọ́run alágbára ni orúkọ rẹ̀. Yóò sì gbe ìjà wa jà, kí ó ba à lè mú wọn wá sinmí ní ilẹ̀ náà; àmọ́ kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Bábílónì.

34

35“Idà lórí àwọn Bábílónì!” ni OLÚWA wí, “lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Bábílónì, àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin.

36Idà lórí àwọn wòlíì èké wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun, wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.

37Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ àti àwọn àjòjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀. Wọn yóò di obìnrin. Idà lórí àwọn ohun ìṣura rẹ̀!

38Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ. Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère, àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.

38

39“Nítorí náà àwọn ẹranko ijù pẹ̀lu ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀, abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀, a kì ó sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé, bẹ́ẹ̀ ni a kì ó ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.

40Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti gba ìjọba Sódómù àti Gòmórà pẹ̀lú àwọn ìlú agbégbé wọn,” ni OLÚWA wí, “kì yóò sí ẹni tí yóò gbé ibẹ̀.

40

41“Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ ogun láti ìhà àríwá; orílẹ̀ èdè ńlá àti àwọn Ọba pípọ̀ ni à ń gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.

42Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun, wọ́n burú wọn kò sì ní àánú. Wọ́n bú bí i rírú omi bí wọ́n ti se ń gun ẹsin wọn lọ. Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì.

43Ọba Bábílónì ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wọn sì rọ, ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.

44Bí i kìnnìún tí ń bú láti igbó Jọ́dánì. N ó lé Bábílónì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kánmọ́ kánmọ́. Ta ni ẹni àyànfẹ́ náà tí n ó yàn? Ta ló dàbí mi, ta ló dàbí mi, ta ló sì le dojú ìjà kọmí?”

45Nítorí náà, gbọ́ ohun tí OLÚWA sọ nípa Bábílónì ẹni tí ó gbìmọ̀ lòdì sí Bábílónì; n ó sì pa agbo ẹran wọn run.

46Ní dídún fèrè Bábílónì gbogbo ilẹ̀ ayé yóò mì tìtì igbe rẹ̀ yóò sì búja gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè.

icle>