Ìwé Wòlíì Jeremáyà 52:1-34 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ṣédékáyà jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ Ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jọba ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútalì ọmọ Jeremáyà; láti Líbíná ló ti wá.

2Ó ṣe búburú ní ojú OLÚWA gẹ́gẹ́ bí Jéhóáikímù ti ṣe

3Nítorí ìbínú OLÚWA ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀. Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọba Bábílónì.

4Nígbà tí ó di ọdún kẹ́sàn án ti Sedekáyà tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹ́wàá, oṣù kẹ́wàá Nebukadinésárì Ọba Bábílónì sì lọ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀.

5Ìlú náà sì wá lábẹ́ ìhámọ́ títí di ọdún kọkànlá Ọba Sédékáyà.

6Ní ọjọ́ kẹ́sàn án, oṣù mẹ́rin ìyàn ìlú náà sì ti burú dé ibi pé kò sí oúnjẹ kankan mọ́ fún àwọn ènìyàn láti jẹ.

7Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ ogun sì tí sálọ. Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrin odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà Ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Àwọn ará Bábílónì yìí yí ìlú náà ká. Wọ́n sá gba aginjù lọ.

8Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ogun Bábílónì lépa Ọba Sedekáyà wọ́n sì le bá ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò. Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì pínyà, kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì túká.

9Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn. Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Bábílónì, ní Ríbíla ní ilẹ̀ Hámátì níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.

10Ní Ríbílà ni Ọba Bábílónì ti pa ọmọkùnrin Sedekáyà lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Júdà.

11Lẹ́yìn náà, o yọ ojú Ṣedekáyà síta, o sì fi ẹ̀wọ̀n yìí dì í, ó sì gbe e lọ sí Bábílónì níbi tí ó ti fi sínú ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n títí di ikú ọjọ́ rẹ̀.

12Ní ọjọ́ kẹ́wàá oṣù kárùn-ún ní ọdún kọkàndínlógún Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù.

13Ó dáná sun pẹpẹ OLÚWA, ààfin àti gbogbo àwọn ilé Jérúsálẹ́mù. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńláńlá.

14Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí wọ́n wà lábẹ́ àṣẹ balógun ìṣọ́ wó gbogbo odi tí ó yí ìlú Jérúsálẹ́mù lulẹ̀.

15Nebusarádánì balógun ìsọ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú náà lọ sí ilẹ̀ àjèjì pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà tí ó kù àti gbogbo àwọn tí ó ti lọ sọ́dọ̀ Ọba Bábílónì.

16Ṣùgbọ́n Nebukadinésárì fi àwọn tálákà tó kú ní ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti oko.

17Àwọn Bábílónì fọ́ idẹ ìpìlẹ̀ àti àwọn ìjókòó tó ṣe é gbé kúrò àti àwọn ìdè wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní pẹpẹ OLÚWA. Wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Bábílónì.

18Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò, ọkọ́ àti ọ̀pá fìtílà, àwọn ọpọ́n, síbí àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ.

19Balógun àwọn ìṣẹ́ náà kó àwokòtò, ohun ìfọná, ọpọ́n ìkòkò, ọ̀pá fìtílà, síbí àti ago wáìnì; èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.

20Àwọn ọ̀wọ̀n méjì agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbèéká tí ó ṣe fún ibi pẹpẹ OLÚWA, èyí tí ó kọjá èyí tí a lè gbéléwọ̀n.

21Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ̀n yìí ni o nà mí, ìwọn ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún tí fífẹ̀ rẹ̀ sì tó ìgbọ̀nwọ́ méjìlá. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú.

22Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èṣo pomegiranátì ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èṣo pomegiranátì tí ó jọra.

23Pomegiranátì mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranátì sì jẹ́ ọgọ́rùn ún kan.

24Balógun àwọn ẹ̀sọ́ mu Ṣeráyà olórí àwọn àlùfáà àti Ṣefanáyà tí ó jẹ́ igbá kejì rẹ̀ àti gbogbo àwọn asọ́nà.

25Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú alásẹ tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn Ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà.

26Nebusaradánì balógun náà kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn lọ sọ́dọ̀ Ọba Bábílónì ní Ríbílà.

27Ní Ríbílà ni ilẹ̀ Hámátì Ọba náà sì pa wọ́n. Báyìí ni Júdà sì sá kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

28Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadinésárì kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì.

28Ní ọdún keje ẹgbẹ̀dógún ó lé mẹ́talélógún ará Júdà.

29Ní ọdún kejìdínlógún Nebakadinésárì

29o kó ẹgbẹ̀rún ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n láti Jérúsálẹ́mù.

30Ní ọdún kẹtàlélógún ènìyàn Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún.

30Júù tí Nebukadinésárì kó lọ sí ilẹ̀ àjòjì jẹ́ márùn ún.

31Ní ọdún kẹtàdín lógójì ti Jéhóáíkímù Ọba Júdà ni Efili-merodaki di Ọba Bábílónì. Ó tú Jéhóáíkímù Ọba Júdà sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kéjìlá.

32Ó ń sọ̀rọ̀ rere sí i, ó sì fún un ní ìjókòó ìgbéga, èyí tí ó ju ti àwọn Ọba yóòkù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì.

33Nítorí náà, Jéhóáíkímù bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n rẹ̀ ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ fún ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀: Ó sì ń jẹun lórí àga Ọba.

34Ní ojoojúmọ́ ni Ọba Bábílónì ń fún Jéhóáíkímù ní ìpín tirẹ̀ títí ọjọ́ ayé rẹ̀ tí ó fi kú.

icle>