1Nígbà náà, ni mo wí pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jákọ́bù,ẹ̀yin alákòóso ilé Ísírẹ́lì.Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ha ṣe láti mọ òdodo bí.
2Ẹ̀yin tí ó kórìíra ire, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi;Ẹ̀yin tí ẹ fa awọ-ẹran ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọnàti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;
3Àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi,wọn sì bọ́ awọ-ara wọn kúrò lára wọn.Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́;Wọn sì gée sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò,bí ẹran inú òdù?”
3
4Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí OLÚWA,Ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn.Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn,nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.
5Báyìí ni OLÚWA wí: “Ní ti àwọn Wòlíìtí ń sí àwọn ènìyàn mi lọ́nà,tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ,wọn yóò kéde àlàáfíà;Ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu,wọn yóò múra ogun sí i.
6Nítorí náà òru yóò wá sórí yín,tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan,òkùnkùn yóò sì kùn fún yín,tí ẹ̀yin kì yóò sì lè ṣọ tẹ́lẹ̀Oòrùn yóò sì yọ lórí àwọn wòlíìọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.
7Ojú yóò sì ti àwọn Wòlíìàwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú.Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn,nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
7
8Ṣùgbọ́n ní tèmi,èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mi OLÚWA,láti sọ ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù fún-un,àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fún-un.
9Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jákọ́bù,àti ẹ̀yin alákòóso ilé Ísírẹ́lì,tí ó kórìíra òdodotí ó sì yí òtítọ́ padà;
10Tí ó kọ́ Síónì pẹ̀lú ìtàjẹ̀sílẹ̀,àti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ìwà búrurú.
11Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó-ọ̀yààwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nítorí owó.Ṣíbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, wọ́n sì wí pé,“Ní tòótọ́, OLÚWA wà pẹ̀lú wa!Ibi kan kì yóò bá wa.”
12Nítorí náà, nitorí tiyín,ni a ó ṣe ro Síónì bí oko,Jérúsálẹ́mù yóò sì di ebèàti òkè tẹ́ḿpìlì bí i ibi gíga igbo.