Ìwé Wòlíì Míkà 4:1-13 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé OLÚWA lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.

2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLÚWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa ó sì máa rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀.” Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde wá, àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti Jérúsálẹ́mù.

3Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jínjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtùlẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ nípa ogun jíjà mọ́.

4ⓑ Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnikan kì yóò sì dẹ́rù bà wọ́n, nítorí OLÚWA àwọn ọmọ ogun ti sọ̀rọ̀.

5Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ OLÚWA. Ọlọ́run wa láé àti láéláé.

6“Ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí, “Èmi yóò kó àwọn arọ jọ; èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ, àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú.

7Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tó kù, èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára. OLÚWA yóò sì jọba lórí wọn ní òkè-ńlá Síónì láti ìsinsìn yìí lọ àti títí láéláé.

8Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Síónì, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín; ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù.”

8

9Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí? Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí? Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí.

10Má a yí síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Síónì, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsìn yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó. Ìwọ yóò lọ sí Bábílónì; níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà. Níbẹ̀ ni OLÚWA yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.

10

11Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́, Ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Síónì!”

12Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú OLÚWA; Bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.

12

13“Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Síónì, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátakó rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orilẹ̀-èdè pátapáta.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún OLÚWA àti ọrọ̀ wọn sí OLÚWA gbogbo aye.