1Ẹ fi etí sí ohun tí OLÚWA wí: “Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá; sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèkéé gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí.
2Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn OLÚWA; gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayerayé. Nítorí OLÚWA ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́; òun yóò sì bá Ísírẹ́lì rojọ́.”
3“Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín? Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn.
4Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mósè láti darí yín bákan náà mo rán Árónì àti Míríámù ṣíwájú rẹ̀.
5Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Bálákì ọba Móábù gbèrò àti ohun tí Bálámù ọmọ Béórì dáhùn. Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣítímù dé Gígálì, kí ìwọ ba le mọ òdodo OLÚWA.”
5
6Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú OLÚWA tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga? Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?
7Ǹjẹ́ OLÚWA yóò ní inúdídùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò, tàbí sí ẹgbẹgbàárùn-ún ìṣàn òróró? Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi, èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?
8Ó ti fi hàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí í ṣe rere, àti ohun tí OLÚWA ń béèrè lọ́wọ́ rẹ? Ṣùgbọ́n láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.
9Gbọ́! Ohùn OLÚWA kígbe sí ìlú ńlá náà, ọlọgbọ́n yóò sì rí orúkọ rẹ̀! “Ẹ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án
10Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búrurú ha wà ní ilé ènìyàn búrurú ṣíbẹ̀, àti òṣùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú?
11Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òṣùwọ̀n búrurú, pẹ̀lú àpò òṣùwọ̀n ẹ̀tàn?
12Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá; àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn?
13Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìṣàn ní lílù ọ́, láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
14Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó; ìyàn yóò wà láàrin rẹ; Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò làìléwu, nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà.
15Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè ìwọ yóò tẹ ólífì, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ; ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì.
16Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omiri mọ́, àti gbogbo iṣẹ́ ilé Áhábù, tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn, nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà; ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.”