1Ègbé ni fún mi! Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ, ìpèsè ọgbà àjàrà; kò sì sí odidi àjàrà kankan láti jẹ, kò sì sí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.
2Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà, kò sì sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòótọ́; gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀sílẹ̀, olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀.
3Ọwọ́ wọn méjèèje ti múra tán láti ṣe búburú; àwọn alákóso ń bèèrè fún ẹ̀bùn, àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́, gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀.
4Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ. Ọjọ́ àwọn olùsọ́ rẹ̀ ti dé, àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò. Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn.
5Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́; ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan. Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni tí ó sùn ní oókan-àyà rẹ.
6ⓐ Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀ ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀, aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀, ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.
7Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní wòye ní ìrètí sí OLÚWA, Èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.
8Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi; Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde. Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn OLÚWA yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi.
9Nítorí èmi ti dẹ́sẹ̀ sí i, Èmi yóò faradà ìbínú OLÚWA, títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi. Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀; èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.
10Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, “Níbo ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ wà?” Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀; nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó.
10
11Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé, ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré.
12Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ láti Ásíríà àti ìlú ńlá Éjíbítì àní láti Éjíbítì dé Yúfúrátè láti òkun dé òkun àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.
13Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé ìnú rẹ̀, nítorí èso ìwà wọn.
14Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ, èyí tí ó ń dáágbé nínú igbó ní àárin kámẹ́lì; Jẹ̀ kí wọn jẹun ní Básánì àti Gílíádì bí ọjọ́ ìgbàànì.
14
15“Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Éjíbítì wá, ni èmi yóò fi ohun-ìyanu hàn án.”
16Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n, nínú gbogbo agbára wọn. Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn, etí wọn yóò sì di.
17Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò, wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló. Wọn yóò bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run wa, wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.
18Ta ni Ọlọ́run bí ì rẹ̀, ẹni tí ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn, tí ó sì fojú fo ìrékọjá èyí tó kù ìní rẹ̀? Kì í dúró nínú ìbínú rẹ̀ láéláé nítorí òun ní inú dídùn sí àánú.
19Òun yóò tún padà yọ́nú sí wa; òun yóò tẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀, yóò sì fa gbogbo àìṣedéédéé wa sínú ibú òkun.
20ⓑ Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jákọ́bù ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Ábúráhámù, bí ìwọ se búra fún àwọn baba wa láti ọjọ́ ìgbà a nì.