Ìwé Wòlíì Náhúmù 3:1-19 BYB2014 - Bible AI

1Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì, gbogbo rẹ̀ kún fún èké, àti olè, ìja kò kúrò!

2Ariwo pàṣán àti ariwo kíkùn kẹ̀kẹ́ ogun àti jíjó ẹṣin àti gbígbọ̀n kẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì!

3Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára ju ìdà wọn mọ̀nàmọ̀nà ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú; òkú kò si ni òpin; àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú.

4Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn panṣágà àgbèrè tí ó rójú rere gbà, Iyá àjẹ́ tí ó sọ́ àwọn orilẹ̀-èdè di ẹrú nipa àgbèrè rẹ̀ àti àwọn ìdílé nipa ìṣe àjẹ́ rẹ̀.

5“Èmi dojú kọ ọ́,” ni OLÚWA awọn ọmọ ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ ìtẹ́lẹ̀dì rẹ ní ojú rẹ, Èmi yóò sì fi ìhòòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba.

6Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́ èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà.

7Kò sí ṣe pé, gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Nínéfè ṣòfò: Ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?”

7

8Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tébésì lọ, èyí tí ó wà ní ibi odò, Náílì tí omi sì yí káàkiri? Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀, omi si jẹ́ odi rẹ̀.

9Etiópíà àti Éjíbítì ni agbára rẹ, kò sí ní òpin; Pútì àti Líbíà ni àwọn olùgbèjà rẹ̀.

10Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn o sì lọ sí oko ẹrú. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ ní orí ìta gbogbo ìgboro. Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin, gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè

11Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara; a ó si fi ọ́ pamọ́ ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà.

11

12Gbogbo ilé-ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn; Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n, ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.

13Kíyè sí, Obínrin ni àwọn ènìyàn rẹ ní àárin! Ojú ibodè rẹ ní a ó sí sílẹ̀ gbagada, fún àwọn ọ̀tá rẹ̀; iná yóò jó ilẹ̀ rẹ

13

14Ìwọ pọn omi de ìhámọ́, mú ile ìsọ́ rẹ lágbára sí i wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀, kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.

15Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run; Idà yóò sì ké ọ kúrò, yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò, yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata, àní, di púpọ̀ bí eṣú!

16Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀ títí wọn yóò ṣe pọ̀ ju ìràwọ̀ oju ọ̀run lọ Kòkòrò na ara rẹ̀ ó sì fò lọ.

17Àwọn aládé rẹ̀ dàbí eṣú, àwọn ọ̀gágun rẹ dàbí ẹlẹ́ǹgà ńlá, èyí ti ń dó sínú ọgbà la ọjọ́ òtútù, ṣùgbọ́n nígbà tí òòrùn jáde, wọ́n sá lọ ẹnìkan kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé wà.

17

18Ìwọ ọba Ásíríà, àwọn olùṣọ àgùntàn rẹ̀ ń tòògbé; awọn ọlọ́lá rẹ yóò máa gbé inú ekuru. Rẹ àwọn ènìyàn rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè ńlá, tí ẹnikẹni kò sì kó wọn jọ.

19Kò sì sí ohun tí ó lè wo ọgbẹ́ ẹ rẹ sàn; ọgbẹ́ rẹ kun fún ìrora Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ ìròyìn rẹ yóò pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí ni orí ta ni, ìwà buburu rẹ kò ti kọjá nígbà gbogbo?

e>