1
2
3
4Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́-ẹran àbọ́pa.
5Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún OLÚWA, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn.
6Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni OLÚWA wí, “Ṣí kíyèsí í, èmi yóò fi olúkúlúkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.”
7Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòsì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì ṣọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́-ẹran náa.
8Olùṣọ àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan;
9Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.”
10Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ ẹ méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mu mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá.
11Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòsì nínú ọ̀wọ́-ẹran náà ti o dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ OLÚWA ni.
12
13OLÚWA sì wí fún mi pé, “Ṣọ ọ sí àpótí ìsúra!” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owo fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìsúra ní ilé OLÚWA.
14Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrin Júdà àti láàrin Íṣírẹ́lì.
15OLÚWA sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun-èlò Olùṣọ́-àgùntàn búburú kan ṣọ́dọ̀ rẹ̀.
16Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dídé ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyi tí ó ni ọ̀rá, yóò sì fa èékánna wọn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
17