1Ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀,
2Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”
3
4Mo sì dáhùn mo sì wí fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, OLÚWA mi?”
5Ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”
6Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA sí Serubábélì tó wí pé: ‘Kìí ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò se nípa Ẹ̀mí mi,’ ni OLÚWA àwọn Ọmọ-ogun wí
7“Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubábélì: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún-un Ọlọ́run bùkún-un!’ ”
8Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ mí wá, wí pé:
9“Ọwọ́ Serubábélì ni a ti ṣe ipilẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.
10
11Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi ólífì méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”
12Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.”
13Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”
14Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti OLÚWA gbogbo ayé.”