1Ọ̀rọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá, wí pé,
2Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńlá-ńlá ni mo jẹ fún Síónì, pẹ̀lú ìbínú ńlá-ńlá ni mo fi jowú fún un.”
3Báyìí ni OLÚWA wí: “Mo yípadà sí Síónì èmi ó sì gbé àárin Jérúsálẹ́mù: Nígbà náà ni a ó sì pé Jérúsálẹ́mù ni ìlú ńlá otítọ́; àti òkè-ńlá OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè-ńlá mímọ́.”
4Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jérúsálẹ́mù, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó.
5Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdé-bìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”
6Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanú ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyánú ni ojú mi bí?” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.
7Báyìí ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Kiyesi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn.
8Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárin Jérúsálẹ́mù: wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”
9Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé OLÚWA àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹ́ḿpìlì.
10Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olukuluku kọ aládùúgbò rẹ̀.
11Ṣùgbọ́n ní ìṣinṣinyìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.
12“Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀: àjàrà yóò ṣo èṣo rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí.
13Yóò ṣi ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrin àwọn aláìkọlà, ẹ̀yin ilé Júdà, àti ilé Íṣrẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún: ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”
14Nítorí báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà.
15“Bẹ́ẹ̀ ni èmi ṣí tí ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jérúsálẹ́mù, àti fún ilé Júdà: ẹ má bẹ̀rù.
16
17Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkeji rẹ̀; ẹ má fẹ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni OLÚWA wí.
18Ọ̀rọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.
19Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ààwẹ̀ oṣù kẹrin, ìkárun-un, kéje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀, àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Júdà; nítorí náà, ẹ fẹ́ otítọ́ àti àlàáfíà.”
20Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn ènìyàn yóò ṣa tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú-ńlá púpọ̀.
21Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú-ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojú rere OLÚWA, àti láti wá OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’
22Nítòótọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ní Jérúsálẹ́mù; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojú rere OLÚWA.”
23Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”