Jákọ́bù 2:1-26 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ nínú ògo Olúwa wá Jésù Kírísítì, ẹ máa ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni.

2Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí talákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí;

3Tí ẹ̀yin sì bu ọla fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún talákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi;”

4Ẹ̀yin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí?

5Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn talákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ?

6Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu talákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n ẹ̀yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́?

7Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?

8ⓐ Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára.

9Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsáájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin.

10Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀.

11ⓑ Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Má ṣe ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Má ṣe pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin.

12Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́.

13Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú; àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́.

14Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí?

15Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́,

16Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́?

17Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀.

18Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́:” Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi.

19Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wá rìrì.

20Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni?

21ⓒ Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Ábúrámù baba wa láre, nígbà tí ó fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ?

22Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé.

23ⓓ Ìwé mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Ábúrámù gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

24Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan.

25ⓔ Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Ráhábù panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn amí, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn?

26Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>