Jóṣúà 11:1-23 BYB2014 - Bible AI

1Nígbà tí Jábínì ọba Hásórù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó ránṣẹ́ sí Jóbábù ọba Madónì, sí ọba Ṣímírónì àti Ákíṣáfù,

2àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúsù ti Kínérótù, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafotu Dórì ní ìwọ̀-oòrùn;

3sí àwọn ará Kénánì ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Ámórì, Hítì, Pérísì àti Jébúsì ní orí òkè; àti sí àwọn Hífì ní ìsàlẹ̀ Hámónì ní agbégbé Mísípà.

4Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun

5Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Mérómù láti bá Ísírẹ́lì jà.

6OLÚWA sì sọ fún Jóṣúà pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ní pípa. Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

7Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yọ sí wọn ní òjijì ní ibi omi Meromù, wọ́n sì kọlù wọ́n,

8OLÚWA sì fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sídónì ńlá, sí Mísíréfótì-Máímù, àti sí Àfonífojì Mísípà ní ìlà-óòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀.

9Jóṣúà sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ: Ó sì já iṣan ẹ̀yìn ẹsẹ̀ ẹṣin wọn ó sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.

10Ní àkókò náà Jóṣúà sì padà sẹ́yìn, ó sì ṣẹ́gun Hásórù, ó sì fi idà pa ọba rẹ̀. (Hásóri tí jẹ́ olú fún gbogbo àwọn ìlú wọ̀nyí Kó tó di àkókò yí.)

11Wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀. Wọ́n sì pa wọ́n run pátapáta, wọn kò sì fi ohun alàyè kan sílẹ̀; ó sì fi iná sun Hásóri fúnrarẹ̀.

12Jóṣúà sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA ti pàṣẹ.

13Sí bẹ̀ Ísírẹ́lì kò sùn ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kékèké, àyàfi Hásórì nìkan tí Jóṣúà sun.

14Àwọn ará Ísírẹ́lì sì kó gbogbo ìkógún àti ohun ọ̀sìn ti ìlú náà fún ara wọn. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo ènìyàn títí wọ́n fi run wọ́n pátapáta, kò sí ẹni tí ó wà láàyè.

15Bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mósè pàṣẹ fún Jóṣúà, Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí OLÚWA pàṣẹ fún Mósè.

16Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà gba gbogbo ilẹ̀ náà: ilẹ̀ òkè, gbogbo Nẹ́gébù, gbogbo agbégbé Gósénì, ẹsẹ̀ òkè ti ìwọ̀-oòrùn, aginjù àti àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ísírẹ́lì,

17láti òkè Hálakì títí dé òkè Séírì, sí Báálì-Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì ní ìsàlẹ̀ òkè Hámónì. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n.

18Jóṣúà sì mú gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí jagun ní ọjọ́ pípẹ́.

19Kò sí ìlú kan tí ó bá àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àdéhùn àlàáfíà, àyàfi àwọn ará Hífì tí wọ́n ń gbé ní Gíbíónì, gbogbo wọn ló bá a jagun.

20Nítorí OLÚWA fúnrà rẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Ísírẹ́lì jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátapáta, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.

21Ní àkókò náà ni Jóṣúà lọ tí ó sì run àwọn ará Ánákì kúrò ní ilẹ̀ òkè, láti Hébúrónì, Débírì, àti ní Ánábù, àti gbogbo ilẹ̀ Júdà, àti kúrò ní gbogbo ilẹ̀ òkè Ísírẹ́lì. Jóṣúà sì run gbogbo wọn pátapáta àti ìlú wọn.

22Kò sí ará Ánákì kankan tí ó sẹ́kù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì: bí kò ṣe ní Gásà, Gátì àti Ásídódù.

23Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà sì gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè, ó sì fi fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀-ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nípa ẹ̀yà wọn.

23Ilẹ̀ náà sì sinmi ogun.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>