1ⓐ Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, láti Ánónì-Gọ́gi dé Okè Hámónì, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:
2Síhónì ọba àwọn Ámorì,tí ó jọba ní Hésíbónì. Ó ṣe àkóso láti Ároérì tí ń bẹ ní etí Anoni-Gọ́gì, láti àárin Jọ́ọ́jì dé Odò Jábókì, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ámónì. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gílíádì.
3Ó sì se àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kínẹ́rétì sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Bẹti-Jésímótù, àti láti gúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Písígà.
4Àti agbégbé Ógù ọba Básánì,ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Ráfíátì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù àti Édírì.
5Ó se àkóso ní orí Okè Hámónì, Sálékà, Básánì títí dé ààlà àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, àti ìdajì Gílíádì dé ààlà Síhónì ọba Hésíbónì.
6Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì borí wọn. Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, àwọn ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.
7Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, láti Báálì Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì sí Okè Hálákì, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Sérì (Jóṣúà sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:
8ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní asálẹ̀ àti Négéfi ilẹ̀ àwọn ará: Hítì, Ámórì, Kénánì, Pérísì, Hífì àti àwọn ará Jébúsì):
9ọba Jẹ́ríkò — ọ̀kan ọba Áì (tí ó wà nítòòsí Bétélì) — ọ̀kan
10ọba Jérúsálẹ́mù — ọ̀kan ọba Hébúrónì — ọ̀kan
11ọba Jámútù — ọ̀kan ọba Lákíṣì — ọ̀kan
12ọba Égílónì — ọ̀kan ọba Gésérì — ọ̀kan
13ọba Débírì — ọ̀kan ọba Gédérì — ọ̀kan
14ọba Hómà — ọ̀kan ọba Árádì — ọ̀kan
15ọba Líbínà — ọ̀kan ọba Ádúlámù — ọ̀kan
16ọba Mákedà — ọ̀kan ọba Bétélì — ọ̀kan
17ọba Tápuà — ọ̀kan ọba Héférì — ọ̀kan
18ọba Áfẹ́kì — ọ̀kan ọba Lásárónì — ọ̀kan
19ọba Mádónì — ọ̀kan ọba Hásórù — ọ̀kan
20ọba Símírónì-Mérónì — ọ̀kan ọba Ákísáfù — ọ̀kan
21ọba Tánáákì — ọ̀kan ọba Mégídò — ọ̀kan
22ọba Kádésì — ọ̀kan ọba Jókínámù ni Kamẹli — ọ̀kan