Jóṣúà 16:1-10 BYB2014 - Bible AI

1Ìpín ti Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò, ó sì la aṣálẹ̀ kọjá láti ibẹ̀ sí ọ̀nà ihà sí òkè ìlú Bẹ́tẹ́lì.

2Ó sì tẹ̀ṣíwájú láti Bẹ́tẹ́lì (tí í ṣe Lúsì) kọjá lọ sí agbègbè àwọn ará Áríkì ní Atárótù,

3Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn agbègbè àwọn ará Jéfílétì, títí dé ilẹ̀ ìṣàlẹ̀ Bẹti Hórónì, àní dé Gésérì, ó sì parí sí etí òkun.

4Báyìí ni Mànásè àti Éfúráímù, àwọn ọmọ Jósẹ́fù gba ilẹ̀ ìní wọn.

5Èyí ni ilẹ̀ Éfúráímù, ní agbo ilé agbo ilé: Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Ádárì ní ìlà oòrùn lọ sí Okè Bẹti-Hórónì.

6Ó sì lọ títí dé òkun. Láti Míkímétatì ní ìhà àríwá, ó sì yí lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Taanati-Sílò, ó sì kọjá ní ẹ̀bá rẹ̀ lọ sí Jánóà ní ìlà-oòrùn.

7Láti Jánóà ó yípo lọ sí gúsù sí Átarótì àti Náárà, ó sì dé Jẹ́ríkò, ó sì pin sí odò Jọ́dánì.

8Láti Tápúà ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Ráfínì, ó sì parí ní òkun. Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Éfúráímù, ní agbo ilé agbo ilé.

9Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Éfúráímù tí ó wà ní àárin ìní àwọn ọmọ Mánásè.

10ⓐ Wọn kò lé àwọn ara Kénánì tí ń gbé ni Gésérì kúrò, titi di oni yìí ni àwọn ara Kébáni ń gbé láàárin àwọn ènìyàn Éfúráímù, Ṣùgbọ́n wọ́n mú wọ́n sìn.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>