Jóṣúà 18:1-28 BYB2014 - Bible AI

1Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì péjọ ní Ṣílò, wọ́n si kó Àgọ́ Ìpàdé ní ibẹ̀ Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn,

2ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò tí ì gba ogún ìní wọn.

3Báyìí ni Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí OLÚWA, Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín?

4Ẹ yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Èmi yóò rán wọn jáde láti lọ bojúwo ilẹ̀ náà káàkiri, wọn yóò sì ṣe àpèjúwe rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìní ẹni kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà ni wọn yóò padà tọ̀ mí wá.

5Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Júdà dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúsù àti ilé Jósẹ́fù ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá.

6Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ gègé fún yín ní iwájú OLÚWA Ọlọ́run wa.

7Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Léfì kò ní ìpín ní àárin yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. OLÚWA ni ìní wọ́n. Gádì, Rúbẹ́nì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jọ́dánì. Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA ti fi fún wọn.”

8Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Jóṣúà pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà kákiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, èmi yóò sì fún yin ní ibí ní Sílòi ní iwájú OLÚWA.”

9Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Jóṣúà lọ ní ibùdó ní Ṣílò.

10Jóṣúà sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Sílò ní iwájú OLÚWA, Jóṣúà sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀.

11Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, ní agbo ilé, agbo ilé. Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàárin ti ẹ̀yà Júdà àti Jósẹ́fù:

12Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jọ́dánì, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jẹ́ríkò ní ìhà àríwá, ó sì forílé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí asálẹ̀ Bẹti-Áfẹ́nì.

13Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúsù ní ọ̀nà Lúsì, (èyí ni Bẹ́tẹ́lì) ó sìdé Afaroti-Ádárì, ní orí òkè tí ó wà ní gúsù Bẹti-Hórónì

14Láti òkè tí ó kọjú sí Bẹti-Hórónì ní gúsù ààlà náà yà sí gúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Báálì (tí í ṣe Kiriati-Jéárímù), ìlú àwọn ènìyàn Júdà. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.

15Ìhà gúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jéárímù ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nẹ́fítóà.

16Ààlà náà lọ sí ìṣàlẹ̀ ẹṣẹ̀ òkè tí ó kọjú sí Àfonífojì Bẹni-Hínómù, àríwá Àfonífojì Réfáímù O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Àfonífojì Hínómù sí apá gúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jébúsì, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé Ẹbi Rósẹ́lì.

17Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni Ṣẹ́mẹ́sì, ó tẹ̀ṣíwájú dé Gélíótì tí ó kọjú sí òkè Pasi Ádúmímù, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Okúta Bóhánì ọmọ Rúbẹ́nì.

18Ó tẹ̀ṣíwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Árábà, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù.

19Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Hógíládì, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jọ́dánì ní gúsù. Èyí ni ààlà ti gúsù.

20Odò Jọ́dánì sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn. Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó ṣàmì sí ìní àwọn ìdílé Bẹ́ńjámínì ní gbogbo àwọn àyíká wọn.

21Ẹyà Bẹ́ńjámínì ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí: Jẹ́ríkò, Bẹti-Hógílà, Emeki-Késísì,

22Bẹti-Árábà, Sẹ́máráímù, Bẹ́tẹ́lì,

23Áfímù, Párà, Ófírà

24Kẹ́fárì, Ámónì, Ófínì àti Gébà, àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn.

25Gíbíónì, Rámà, Béérótì,

26Mísípà, Kéfírà, Mósà,

27Rẹ́kẹ́mù, Írípẹ́ẹ́lì, Tárálà,

28Sélà, Háléfì, ìlú Jébúsì (tí íse Jérúsálẹ́mù), Gíbíà àti Kíríátì, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn.

28Èyí ni ìní Bẹ́ńjámínì fún ìdílé rẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>