1Gègé kéjì jáde fún ẹ̀yà Símíónì, ní agbo ilé, ní agbo ilé. Ìní wọn sì wà ní àárin ilẹ̀ Júdà.
2Lára ìpín wọn ní:
3Hasari-Ṣúálì, Báláhì, Ésémù,
4Élítóládì, Bétúlì, Hómà,
5síkílágì, Bẹti-Mákábótì, Hasari-Súsà,
6Bẹti-Lébà ati Ṣárúẹ́nì, ìlú wọn jẹ́ mẹ́talá àti ìletò wọn.
7Háínì, Rímónì, Étérì àti Áṣánì: Ìlú wọn jẹ́ mẹ́rin àti ìletò wọn:
8Àti gbogbo àwọn agbégbé ìlú wọ̀nyí títí dé Baalati-Béérì (Rámà ní Négéfì).
9A mú ogún ìní àwọn ọmọ Símíónì láti ìpín Júdà, nítorí ìpín Júdà pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ. Báyìí ni àwọn ọmọ Símíónì gba ìní wọn ní àárin ilẹ̀ Júdà.
10Gègé kẹ́ta jáde fún Sébúlunì, ní agbo ilé ní agbo ilé:
11Ó sì lọ sí ìwọ̀-oòrùn ní Márálà, ó sì dé Dábésẹ́tì, ó sì lọ títí dé Ráfénì odo ní ẹ̀bá Jókíníámù.
12Ó sì yípadà sí ìlà-oòrùn láti Sérídì sí ìhà ìlà-oòrùn dé ilẹ̀ Kisiloti-Tábórì, ó sì lọ sí Dábérátì, ó sì gòkè lọ sí Jáfíà.
13Nígbà náà ní o lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Gati-Héférì àti Eti-Kásínì, ó sì jáde ní Rímónì, ó sì yí sí ìhà Níà.
14Ní ibẹ̀, ààlà sì yí ká ní ìhà àríwá lọ sí Hánátónì ó sì pin ní Àfonífojì Ifita Élì.
15Lára wọn ni Kátatì, Náhalálì, Símírónì, Ìdálà àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlá àti ìletò wọn.
16Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní Sébúlunì, ní agbo ilé agbo ilé.
17Gègé kẹrin jáde fún Ísákárì, agbo ilé ní agbo ilé.
18Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:
19Háfáráímù, Ṣíhónì, Ánáhárátì,
20Rábítì, Kíṣíónì, Ébésì,
21Rémétì, Ẹni-Gánnímù, Ẹni-Hádà àti Bẹ́tì-Pásésì.
22Ààlà náà sì dé Tábórì, Ṣáhásúmà, àti Bẹti Ṣẹ́mẹ́ṣì, ó sì pin ní Jọ́dánì. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rindínlógún àti iletò wọn.
23Ìlú wọ̀nyí àti iletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Ísákárì, ní agbo ilé agbo ilé.
24Gègé karùnún jáde fún ẹ̀yà Áṣíérì, ní agbo ilé agbo ilé.
25Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:
26Álàmélékì, Ámádì, àti Míṣálì. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Kámẹ́lì àti Ṣíhórì-Líbínátì.
27Nígbà náà ni o yí sí ìhà ilà-oòrùn Bẹti-Dágónì, dé Sébúlúnì àti Àfonífojì Ífíta-Élì, ó sì lọ sí àríwá sí Bẹti-Ẹ́mẹ́kì àti Néíélì, ó sì kọjá lọ sí Kábúlì ní apá òsì.
28Ó sì lọ sí Ábídónì, Réóbù, Hámónì àti Kánà títí dé Sídónì ńlá.
29Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rámà, ó sì lọ sí ìlú olódi Tirè, ó sì yà sí Hósà, ó sì jáde ní òkun ní ilẹ̀ Ákísíbì,
30Úmà, Áfẹ́kì àti Réóbù. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlélógún àti ìletò wọn.
31Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Áṣíérì, ní agbo ilé agbo ilé.
32Ìpín kẹfà jáde fún Náfítalì, agbo ilé ní agbo ilé:
33Ààlà wọn lọ láti Hẹ́lẹ́fì àti igi ńlá ní Sááná nímù; kọjá lọ sí Ádámì Nékébù àti Jábínẹ́ẹ́lì dé Lákúmì, ó sì pín ní Jọ́dánì.
34Ààlà náà gba ìhà ìwọ̀-oòrùn lọ sí Ásínótì, Tabori ó sì jáde ní Húkókì. Ó sì dé Sébúlúnìe ní ìhà gúsù, Ásíẹ́rì ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Jọ́dánì ní ìhà ìlà-oòrùn.
35Àwọn ìlú olódi sì Sídímù, Sérì, Hámátì, Rákátì, Kínérétì,
36Ádámà, Rámà Hásórì,
37Kédéṣì, Édíréì, Ẹ́ní-Hásórì,
38Írónì, Mígídálì-Élì, Hórémù, Bẹ́tì-Ánátì àti Bẹ́tì-Sẹ́mẹ́ṣì. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mọ́kàndínlógún àti ìletò wọn.
39Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Náfitalì, ní agbo ilé sí agbo ilé.
40Ìbò keje jáde fún ẹ̀yà Dánì, ní agbo ilé ní agbo ilé.
41Ilẹ̀ ìní wọn nì wọ̀nyí:
42Ṣáálábínì, Áíjálónì, Ítílà,
43Élónì, Tímínà, Ékírónì,
44Élítékè, Gíbétónì, Báálátì,
45Jéúdì, Béné-Bérákì, Gátí-Rímónì,
46Mé Jákónì àti Rákónì, pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó kọjú sí Jópà.
47(Ṣùgbọ́n àwọn ará Dánì ní ìsoro láti gba ilẹ̀-ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Lẹ́ṣẹ́mù, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Lẹ́sẹ́mù, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì orúkọ baba ńlá wọn).
48Àwọn ìlú wọ̀n yí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Dánì, ní agbo ilé agbo ilé.
49Nígbà tí wọ́n ti parí pínpín ilẹ̀ náà ní ìpín ti olúkúlùkù, àwọn ará Ísírẹ́lì fún Jóṣúà ọmọ Núnì ní ìní ní àárin wọn
50Bí OLÚWA ti pàṣẹ, wọ́n fún-ún ni ìlú tí ó béèrè fún—Tímínátì Sérà ní ìlú òkè Éfúráímù. Ó sì kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé ibẹ̀.
51Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Élíásárì àlùfáà, Jósúà ọmọ Núnì àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Ísírẹ́lì fi ìbò pín ní Sílò ní iwájú OLÚWA ní ẹnu-ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.