1
2Ní Sílò, ní Kénánì, wọn sọ fún wọn pé, “OLÚWA pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”
3Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní ti wọn gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.
4Ìpín kìn-ín-ni wà fún àwọn ọmọ Kóhátì, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Árónì àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara Símónì àti Bẹ́ńjámínì.
5Ìyòókù àwọn ọmọ Kóhátì ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù, Dánì àti ìdajì Mánásè.
6Àwọn ẹ̀yà Gásónì ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara ẹ̀yà Ísákárì, Áṣíérì, Náfitalì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní Básánì.
7Àwọn ọmọ Mérárì ní agbo ilé, agbo ilé ni wọ́n fún ní ìlú méjìlá láti ara ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Sébúlónì.
8Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tutù fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ láti ẹnu Móse.
9Láti ara ẹ̀yà Júdà àti ẹ̀yà Síméónì ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí,
10(Ilú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Árónì tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kóhátì tí í ṣe ọmọ Léfì, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ ti wọn).
11“Wọ́n fún wọn ní Kiriati Áríbà (tí í ṣe, Hébúrónì), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Júdà. (Áríbà ni baba ńlá Ánákì.)
12Ṣùgbọ́n àwọn oko àti àwọn abúlé ní agbégbé ìlú náà ni wọ́n ti fi fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀.
13Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ní Hébúrónì (ọ̀kannínú ìlú ààbò fún àwọn apàníyàn) pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Líbínà,
14Játírì, Ésítẹ́móà,
15Hólónì àti Débírì,
16Háínì, Jútà àti Bẹti-Sẹ́mẹ́sì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn. Ìlú mẹ́sàn án láti ara ẹ̀yà méjì wọ̀nyí.
17Láti ara ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni wọ́n ti fún wọn ní Gíbíónì, Gẹ́bà,
18Ánatótì àti Álímónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.”
19Gbogbo ìlú àwọn àlùfáà, ìran Árónì, jẹ́ mẹ́talá, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá wọn.
20Ìyòókù ìdílé Kóhátì tí ó jẹ́ ọmọ Léfì ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù.
21“Ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù wọ́n fún wọn ní Ṣẹ́kẹ́mù (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn) ati Gésérì,
22Kíbásáímù àti Bẹti-Hórónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.
23Láti ara ẹ̀yà Dánì ní wọ́n ti fún wọn ní Élítékè Gíbátónì,
24Áíjálónìd àti Gati-Rímónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ mẹ́rin.
25Láti ara ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní wọ́n ti fún wọn ní Tánákì àti Gati-Rímónì pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú méjì.”
26Gbogbo ìlú mẹ́wẹ̀wá yìí àti ilẹ̀ pápá wọn ni a fi fún ìyókù ìdílé Kóhátì.
27Àwọn ọmọ Gáṣóní idile àwọn ọmọ Lefi ní wọ́n fún lára:
28Láti ara ẹ̀yà Ísákárì ni wọ́n ti fún wọn ní,
29
30Láti ara ẹ̀yà Ásíérì ni wọ́n ti fún wọn ní
31
32Láti ara ẹ̀yà Náfítanì ni a ti fún wọn ní
33Gbogbo ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Gáṣónì jẹ́ mẹ́talá, pẹ̀lú ilẹ́ pápá oko wọn.
34Láti ara ẹ̀yà Sébúlónì ni a ti fún ìdílé Mérárì (tí í ṣe ìyókù ọmọ Léfì) ní:
35
36Láti ara ẹ̀yà Rúbẹ́nì ni wọ́n ti fún wọn ní
37
38Láti ara ẹ̀yà Gádì ní wọ́n ti fún wọn ní
39Hésíbónì àti Jásérì, e pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.”
40Gbogbo ìlú tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Mérárì tí wọ́n jẹ́ ìyókù àwọn ọmọ Léfì jẹ́ méjìlá.
41Gbogbo ìlú àwọn ọmọ Léfì tó wà láàárin ara ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ méjìdínláádọ́ta lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko wọn.
42Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìlú wọ̀nyí ni ó ni ilẹ̀ pápá oko tí ó yí ì ká, bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ìlú wọ̀nyí.
43Báyìí ni OLÚWA fún Ísírẹ́lì ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí láti fi àwọn fún baba ńlá wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbà á tan wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.
44OLÚWA sì fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí ó ti sèlèrí fún baba ńlá wọn. Kò sì sí ọ̀kankan nínú àwọn ọ̀ta wọn tí ó lè dojú kọ wọ́n. OLÚWA sì fi gbogbo àwọn ọ̀ta wọn lé wọn ní ọwọ́.
45Kò sí ọ̀kan nínú ìlérí rere tí ó se fún ilé Ísírẹ́lì tí ó kùnà. Gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe.