1
2ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe gbogbo èyí tí Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA pàṣẹ, ẹ sì ti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ.
3Ẹ kò fi àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ láti ìgbà yí títí di òní, ṣùgbọ́n ẹ ti kíyèsára láti pa òfin OLÚWA Ọlọ́run yín mọ́.
4Nísinsìn yìí tí OLÚWA Ọlọ́run yín ti fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, ẹ padà sí ilẹ̀ yín níbi tí Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA fi fún yin ní òdì kéjì Jọ́dánì.
5Ṣùgbọ́n ẹ sọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn OLÚWA Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́ràn sí àṣẹ rẹ̀, láti dì í mú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.”
6Nígbà náà ni Jóṣúà súre fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn.
7(Mósè ti fi ilẹ̀ fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní Básánì, Jóṣúà sì ti fún ìdajì ẹ̀yà yóòkù ní ilẹ̀ ní ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn). Jóṣúà súre fún wọn ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn,
8Ó sì wí pé, “Ẹ padà sí ilẹ̀ ẹ yín pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ yín, pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú fàdákà, wúrà, idẹ àti irin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, kí ẹ sì pín ìkógún tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta yín pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín.”
9Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè fi àwọn ará Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní Sílò ní Kénánì láti padà sí Gílíádì, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLÚWA láti ẹnu Mósè wá.
10Nígbà tí wọ́n wá dé Gélílótì ní ẹ̀bá Jọ́dánì ní ilẹ̀ Kénánì, àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jọ́dánì.
11Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti mọ pẹpẹ ní orí ààlà Kénánì ní Gélíótì ní ẹ̀bá Jọ́dánì ní ìhà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,
12gbogbo àjọ Ísírẹ́lì péjọ ní Ṣílò láti lọ bá wọn jagun.
13Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rán Fínéhásì ọmọ Élíásárì àlùfáà, sí ilẹ̀ Gílíádì, sí Rúbẹ́nì, sí Gádì àti sí ìdajì ẹ̀yà Mánásè.
14Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ti wọn jẹ́ olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
15Nígbà tí wọ́n lọ sí Gílíádì-sí Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè wọ́n sì sọ fún wọn pé,
16“Gbogbo àjọ ènìyàn OLÚWA wí pe: ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì nípa yíyí padà kúró lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìsọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí OLÚWA.?
17Ẹ̀sẹ̀ Péórì kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tíì wẹ ara wa mọ́ kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-àrùn ti jà láàárin ènìyàn OLÚWA.!
18Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn OLÚWA ni báyìí.?
19Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní OLÚWA, ní ibi tí àgọ́ OLÚWA dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí OLÚWA tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ OLÚWA Ọlọ́run wa.
20Nígbà tí Ákánì ọmọ Sérà ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọtọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Ísírẹ́lì nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ”
21Nígbà náà ni Rúbénì, Gádì àti ẹ̀yà Mánásè sọ nínú ìdáhùn wọn fún àwọn olórí Ísírẹ́lì pé.
22OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọlọ́run! OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Òun mọ̀ jẹ́ kí Ísírẹ́lì kí ó mọ̀! Bí èyí bá wà ní ìsọ̀tẹ̀ tàbí àìgbọ́ràn sí OLÚWA, ẹ má ṣe dá wa sí ní òní yìí.
23Bí àwa bá ti mọ pẹpẹ wa láti yí padà kúrò ní ọ̀dọ̀ OLÚWA àti láti rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ jíjẹ, tàbí ẹbọ àlàáfíà ní orí rẹ, kí OLÚWA fún ara rẹ̀ gba ẹ̀san
24“Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, ‘Kí ni ẹ̀yín ní ṣe pẹ̀lú OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì?
25OLÚWA ti fi Jódánì ṣe ààlà láàárin àwa àti ẹ̀yin-àwọn ọmọ Réúbénì àti àwọn ọmọ Gádì! Ẹ kò ni ní ìpín nínú OLÚWA.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù OLÚWA.
26“Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, Ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ọrẹ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ.’
27Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàárin àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún OLÚWA ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti OLÚWA.’
28“Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé: Ẹ wo àpẹrẹ pẹpẹ OLÚWA, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ọrẹ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrin àwa àti ẹ̀yin.’
29“Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA, kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ fún ẹbọ sísun ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ OLÚWA Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀.”
30Nígbà tí Fínéhásì àlùfáà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, àwọn olórí ìdílé Ísírẹ́lì gbọ́ ohun tí Réúbẹ́nì, Gádì àti Mánásè ti sọ, ó dùn mọ́ wọn.
31Fínéhásì ọmọ Élieásárì, àlùfáà wí fún Réúbẹ́nì, Gádì àti Mánásè, “Ní òní ni àwa mọ̀ pé OLÚWA wà pẹ̀lú wa, nítorí tí ẹ̀yin kò hùwà àìṣòtítọ́ sí OLÚWA ní orí ọ̀rọ̀ yí nísinsin yìí, ẹ̀yin ti yọ àwọn ará Ísírẹ́ì kúrò ní ọwọ́ OLÚWA”.
32Nígbà náà ni Fínéhásì ọmọ Élíásárì àlùfáà àti àwọn olórí padà sí Kénánì láti ibi ìpàdé wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Réúbẹ́nì àti ẹ̀yà Gádì ní Gílíádì, wọ́n sì mú ìròyìn tọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.
33Inú wọn sì dùn láti gbọ́ ìròyìn náà, wọ́n sì yin Ọlọ́run. Wọn kò sì sọ̀rọ̀ mọ́ nípa lílọ bá wọn jagun láti run ilẹ̀ tí àwọn ẹ̀yà Réúbẹ́nì àti ẹ̀yà Gádì ń gbé.
34Ẹ̀yà Réúbẹ́nì àti ẹ̀yà Gádì sì fún pẹpẹ náà ní orúkọ yìí: “Ẹ̀rí láàárin wa pé OLÚWA ni Ọlọ́run.”