Jóṣúà 3:1-17 BYB2014 - Bible AI

1Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, Jóṣúà ati gbogbo àwọn Ísírẹ́lì sí kúrò ní Sítímù, wọ́n sì lọ sí etí odò Jọ́dánì, wọ́n sì pa ibùdó síbẹ̀ kí wọn tó kọjá.

2Lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́ta àwọn olórí la àárin ibùdó já.

3Wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé: “Nígbà tí ẹ bá rí àpótí i májẹ̀mú OLÚWA, Ọlọ́run yín, tí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì rù ú, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sí kúrò ní ipò o yín, ẹ̀yin yóò sì máa tẹ̀lé e.

4Ẹyin yóò lè mọ ọ̀nà tí ẹ ó gbà, torí pé ẹ̀yin kò gba ọ̀nà yìí tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n àlàfo gbọdọ̀ wà ní àárin yín àti àpótí náà, tó bí ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún un mítà (1000).”

5Jóṣúà sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, OLÚWA yóò ṣe ohun ìyanu ní àárin yín.”

6Jóṣúà sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà, kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn.

7OLÚWA sì sọ fún Jóṣúà pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì; kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lúù rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Móṣè.

8Sọ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà: ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí omi Jọ́dánì, ẹ lọ kí ẹ sì dúró nínú odò náà.’ ”

9Jóṣúà sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ̀yin kí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run yín.

10Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárin yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì, Hífì, Pérésì, Gágáṣì, Ámórì àti Jébúsì jáde níwájú u yín.

11Àpótí ẹ̀rí OLÚWA gbogbo ayé, ń gòkè lọ sí Jọ́dánì ṣáájú u yín.

12Ǹjẹ́ nísinsìn yí, ẹ mú ọkùnrin méjìlá (12) nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

13Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí OLÚWA, OLÚWA gbogbo ayé bá ti ẹṣẹ̀ bọ odò Jọ́dánì, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbájọ bí òkítì kan.”

14Nígbà tí àwọn ènìyàn gbéra láti ibùdó láti kọjá nínú odò Jọ́dánì, àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà ń lọ níwájú wọn.

15Odò Jọ́dánì sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè. Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jọ́dánì, tí ẹṣẹ̀ wọn sì kan etí omi,

16omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbájọ bí òkítì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Ádámù, tí ó wà ní tòsí Sárétanì; nígbà tí omi tí ń ṣàn lọ sínú òkun aginjù, (Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátapáta. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdì kejì ní ìdojúkọ Jẹ́ríkò.

17Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí OLÚWA sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárin Jọ́dánì, nígbà tí gbógbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀ èdè náà fi ré kọjá nínú odò Jọ́dánì lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>