1JÚDÀ, ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì àti arákùnrin Jákọ́bù,
2Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
3Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.
4
5Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́.
6Àti àwọn ańgẹ́lì tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìṣàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ ọjọ́ ńlá nì.
7
8Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjoye, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búbúrú sí àwọn ọlọ́lá.
9
10Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀ òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa ìròfún-ara, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípaṣẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun.
11
12Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àṣè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùsọ́ àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọn tú ti-gbòǹgbò-ti-gbòǹgbò.
13Wọ́n jẹ́ ìjì líle ti ń ru ní ojú omi òkun, ti ń hó ìfófó ìtìjú wọn jáde; alárìnkiri ìràwọ̀, àwọn tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè láéláé.
14
15láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi ní ti gbogbo iṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, ti wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́sẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run ti sọ sí i.”
16Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn; wọn ń gbéraga nipa ara wọn, wọ́n sì ń ṣáta àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn.
17Ṣùgbọ́n ẹyin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ tí a ti sọ ṣááju láti ọwọ́ àwọn Àpósítélì Olúwa wa Jésù Kírísítì.
18
19Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni tí ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí.
20Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́.
21Ẹ máa pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀yin ti ń rétí àánú Olúwa wa Jésù Kírísítì tí yóò mú yín dé ìyè àìnípẹ̀kun.
22Ẹ máa yí àwọn tí ń ṣe iyèméjì lọ́kàn padà:
23
24Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọsẹ̀, tí o sì lè mú yín wá ṣíwájú ògo rẹ̀ láilábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́—
25tí Ọlọ́run ọlọ́gbọn níkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọlá ńlá, ìjọba àti agbára, nísinsìn yìí àti títí láéláé! Àmín.