Títù 1:1-16 BYB2014 - Bible AI

1Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti Àpósítélì Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà bí Ọlọ́run—

2ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti se ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀,

3àti pé ní àkókò tirẹ̀, òun ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn nínú ìwàásù tí a fi lé mi lọ́wọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa.

4ⓐ Sí Títù, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kírísítì Jésù Olùgbàlà wa.

5Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè ni pé kí o lè ṣe àsepé àwọn iṣẹ́ tó sẹ́kù. Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀.

6Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan.

7Alámójútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò.

8Wọ́n ní láti jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, olùfẹ́ ohun tí ó dára. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tí ó kò ara rẹ̀ ní ìjánu, ẹni dúró sinsin, ọlọ́kàn mímọ́, àti ẹni oníwàtítọ́.

9Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nìpa ìdúrósinsin mú dáadáa gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò.

10Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, afínnú àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrin àwọn onílà.

11Ó gbọdọ̀ pawọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí wí pé wọ́n ń pa agbo Ọlọ́run run, nípaṣẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ èyí tí wón ń kọ́ni. Èyí ni wọ́n ń ṣe fún ere àìsòdodo.

12Ọ̀kan nínú àwọn wòlíì wọn pàápàá sọ wí pé, “òpùrọ́ ní àwọn ará Kírétè, wọ́n jẹ́ ẹranko búburú tí kò sé tù lójú, ọ̀lẹ, oníwọ̀ra”.

13Òtítọ́ ni ẹ̀rí yìí. Nítorí náà, bá wọn wí gidigidi, kí wọn baà lè yè koro nínú ìgbàgbọ́

14kí àwọn má ṣe fiyè sí ìtàn lásán ti àwọn Júù, àti òfin àwọn ènìyàn tí wọ́n yípadà kúrò nínú òtítọ́.

15Sí ọlọ́kàn mímọ́, ohun gbogbo ló jẹ́ mímọ́, ṣùgbọ́n àwọn tó ti díbàjẹ́ tí wọ́n kò sí ka ohunkóhun sí mímọ́. Nítòótọ́, ati ọkàn àti ẹ̀rí ọkàn wọn ló ti díbàjẹ́.

16Wọ́n ń fẹnu sọ wí pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ ẹ nípa ìṣe wọn. Wọ́n díbàjẹ́, aláìgbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wúlò lọ́nàkọnà ní ti iṣẹ́ rere gbogbo.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>